When you are in the quest to know sweet Yoruba Oriki for your husband or for your wives, it is compulsory you look inward first, before adoring your hubby with the Eulogy that doesn’t tally with that of his clans.
When praising your husband with his Oriki perhaps after he has done something that makes you happy, you need to research his clan, his village, what are they known for, are they warriors? Blacksmith? Singers? Dancers? Artist? Or they are from a royal family? All of these will contribute to how to praise him and how to dig out his Oriki.
We have Oriki for warriors if he is from that clan, and we have Oriki for royal ones if he is from one, so, before we give you some of the examples we have here, you need to trace your husband’s linage and have detailed information about his origin before you can come up with a meaningful Oriki that will truly arise his ego and makes him want to do more of the goodness he has just done.
So, here are some romantic Oriki for husband praises;
Yoruba Oriki For Husband
Ajisafe (Husband name here)
Agun t’aso lo
Akigbemaru
Duduyemi
Ekiti Husband
Omo owa omo ekun
Omo oro ninu waya agbele sebi eko, aidamo ro o yangba
Omo otiriki ju Ida, ki leri ogun hun won lule owa
Elila oke isha, okan din nibe eyin ra kan si, okan le nibe inse leyin pa kan je
Omo agesin re popo ukoro, Omo ogbogan gbogan leti
Omo aroyin royin kan se po e yo run lule aran
Omo ekun peran dagba aya si, Omo jiwajiwa ileke
Eyin lomo olulu oro kii ro loru. Omo olupepe ka sokasoka ka mebibo sere, ka soloko segbe ogiri lule eyigbo
Eyin lomo irafi eemi, omo agbona bi ado
Omo elewure funfun ilasa ki fun bi okin
Omo obanla ba odo, omo arabaribi okuta
Omo Aalaere gbendeke, Omo aji be gbaa ji
Udile Ekiti Omo aji mogun sano omo opababa lesi lodo ose oko.
Edumare Bawa Da Ule Ekiti Si
Ibadan Man
Ibadan mesi Ogo, nile Oluyole. Ilu Ogunmola, olodogbo keri loju ogun. Ilu Ibikunle alagbala jaya-jaya. Ilu Ajayi, o gbori Efon se filafila. Ilu Latosa, Aare-ona kakanfo. Ibadan Omo ajoro sun. Omo a je Igbin yoo,fi ikarahun fo ri mu. Ibadan maja-maja bii tojo kin-in-ni, eyi too ja aladuugbo gbogbo logun, Ibadan ki ba ni s’ore ai mu ni lo s’ogun.
Ibadan Kure! Ibadan beere ki o too wo o, Ni bi Olè gbe n jare Olohun. B’Ibadan ti n gbonile bee lo n gba Ajoji. Eleyele lomi ti teru-tomo ‘Layipo n mu. Asejire lomi abumu-buwe nile Ibadan. A ki waye ka maa larun kan lara, Ija igboro larun Ibadan.
Akure Man
AKURE OLOYEMEKUN OMO A MUDA SILE MOGUN ENU PA NI OMO OKUNRIN AKURE TOKO BO O FAGADA PERIN OMOBINRIN AKURE TODO BO O FOSIMILO PEFON AKURE MOJO GBEWURA KENI OBA MA HU ESISE RE LO OSI KI TAKURE KO MA LASO ALA ALA EYE MI NINU OKE AKURE LOMI MEJI A NPEJEJI LALA ALA SE BE O DOMI OMO AKURE LOMO OLOJA MEJI KAN AN NA LORUJO KAN AN BA NA TORI TAGUN AN A NA MESI ANAYE. EYIN TEMI LABALA YI MO KI YIN PE EKU FAAJI OJO ISINMI ONI EMI WA A SE PUPO E LAYE
Oriki Omo Egba
Egba mo’lisa
Omo gbongbo akala
Omo erin jogun ola
Omo osi’lekun pa’lekun de
Aridi ogo loju Ogun
Baba teyin na royin ogun baara fagbe
Egba omo aduro gberu, maduro gbeko
Eru ni nsini, eko kin sin’yan
Ko so’hun ti won nse ni mecca
Te’yin ki nse legba Alake yin
Won n mumi semi semi ni Mecca
Eyin n mumi Odo Ogun legba Alake
Won n g’Arafa ni Mecca
Eyin n’gori Olumo l’egba tiyin
Won bi yin L’ake
E’gbo lenu bi jeje
Won bi yin ni Gbagura
E’gbo lohun bi oje.
Edumare bawa da ilu Egba si
Ase
Conclusion
It is not just enough to recite the eulogy or anyhow Oriki for your husband, it is advisable to know the village your husband is from, and the clan he is from, these will give you incite into how they are being eulogized. If you need Oriki for your husband’s state or town, let us know in the comment section, and we will provide them for you.
So, that is all about Yoruba Oriki for husband praises.